Ààrẹ Bùhárí kí àgbà òṣèlú APC, Àkàndé kú ayẹyẹ ọdún kẹrìnlé-lọ́gọ́rin
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti kí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tẹ́lẹ̀,Olóyè Bísí Àkàndé,alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ All Progressives Congress,APC,kú oríire ayẹyẹ ọdún kẹrìnle-lọ́gọ́ta,ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà ìlú tòótọ́ àti ẹni tí ayé fẹ́.
Nínú ìfiránṣẹ́ láti ṣe ayẹyẹ náà, Ààrẹ mọ rírì akitiyan àgbà òṣèlú náà lórí ìjọba tiwantiwa,ẹni tí ó sọ pé ó rí ìgbéga láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ sí ipò tó ga jùlọ nínú òfin òṣèlú nípasẹ̀ ìmúra síṣẹ́ àti ìkóraẹni níjanu.
Ààrẹ Bùhárí sọ wípé olóyè Àkàndé yóò túnbọ̀ máa “jẹ́ àgbà òṣèlú tòótọ́ àti àpẹẹrẹ onífaradà,akíkanjú àti oníwà pẹ̀lẹ́ .”
Ó wá gbàdúrà kí ó gbó,kí ó tọ́ nínú iṣẹ́ ẹgbẹ́ àti orílẹ̀-èdè.
Leave a Reply