Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní gúsù iwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà ti pè fún àtúnṣe ẹ̀ka ààbò Nàìjíríà láti jẹ́ kí wọ́n le ṣe iṣẹ́ tó múnádóko.
Gómìnà Adémọ́lá Adélékè pè ìpè yìí ní ọjọ́ Àìkú, níbi àṣekágbá ayẹyẹ ọdún ìrántí àwọn ọmọ ológun tí ó pàdánù ẹ̀mí wọn lẹ́nu iṣẹ́,ní bojì ọmọ ológun tuntun,ní Òṣogbo,olú-ìlú náà.
Ó pe àkíyèsí sí ipò ààbò ní orílẹ̀-èdè, pé ó fẹ́ àmójútó ní gbogbo ìpele ìjọba ní kíákíá,ó ní àwọn adarí ní láti fọwọ́sowọ́pọ̀ fún ìgbélárugẹ ààbò tó péye fún àwọn ọmọ ológun àti àwọn ẹbí ológun tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Gómìnà náà sọ pé àwọn àṣàyàn ìsúná orílẹ̀-èdè kò gbọdọ̀ dojúkọ ohun èlò ológun nìkan ṣùgbọ́n gbogbo wíwaọ̀ dáradára àwọn òṣìṣẹ́ ológun.
Leave a Reply