Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣèlérí Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Tó Dán Mọ́rán Pẹ̀lú Àwọn Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn

25

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun pinnu láti mú kí ìtẹ̀síwájú alágbára dé bá ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn, nígbà tó ṣèlérí ìṣèjọba to n ko àkóyawọ́.

Ẹni tii ṣe Akọ̀wé Ìjọba, Ọ̀jọ̀gbọ́n Musibau Babátúndé ló sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó n gba àlejò àwọn Adarí Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn (Correspondents’Chapel), tii ṣe ẹ̀ka Àgbáríjọ Ẹgbẹ́ oníròyìn (NUJ) ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni ọ́fíìsì rẹ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Babatunde sọ pé ìbáṣepọ̀ tó wà láàrín ìjọba àti àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láàrin ọdún bíi mẹ́fà sí méje sẹ́yìn jẹ́ èyí tó rọ̀gbọ̀kú lórí ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìbòwọ̀ fún ara ẹni. Ó wá fi àsìkò náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akọ̀ròyìn fún ìwà ìfọmọnìyànṣe, eléyìí tó n farahàn nínú iṣẹ́ ìríjú wọn, nígbà tó ṣèlérí pé ìjọba yóò rí dájú pé wọn wà ojútùú sí àwọn ìpèníjà tí àwọn Akọ̀ròyìn bá gbé kalẹ̀ nípasẹ ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán.

Ṣáájú ní Alága Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn náà, Yinka Adeniran ti ṣàlàyé pé àwọn Adarí Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn (Correspondents’ Chapel Executives) wá ṣe àbẹ̀wò sí Akọwe ìjọba lẹ̀yìn ètò ìdìbò tó yan àwọn alákóso Ẹgbẹ́ náà sípò ní oṣù kínní ọdún yìí. Adeniran wá gbóríyìn fun ìṣèjọba to wa lóde fún àṣeyọrí to tí ṣe láàrin ọdún bíi mẹ́fà sẹ́yìn, nígbà tó ṣàpèjúwe ìṣàkóso ìjọba tó wà lóde ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gẹ́gẹ́ bí eléyìí tó n ṣe àtúnṣe.

Bákan náà, Adeniran fi àsìkò náà kí Akọ̀wé Ìjọba fún ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ láì ka ipò ẹ̀kọ́ àti ipò òṣèlú rẹ̀ sí.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, igbákejì Alága ẹgbẹ́ náà, Remi Koleoso, sọ pé àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn mọ iyì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìjọba pẹ̀lú wọn. Ó fi àsìkò náà ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn náà yíò ṣe àgbédìde ìpàdé gbígba àlejò pàtàkì ni ilé ẹgbẹ́ náà, ètò tó máa n wáyé ni oṣooṣù, nínú èyí tí àwọn ènìyàn olókìkí tí wá bá àwọn akọ̀ròyìn ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀.

Igbákejì Alága wa rọ ìjọba pé kí wọ́n rí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́ pọ̀, nigba tó pe fún ìbáṣepọ̀ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọlọjọ pípẹ́.

 

Abiola Olowe

Ìbàdàn.

Comments are closed.

button