Gomina Ipinle Adamawa Ahmadu Fintiri ti fi egbe Peoples Democratic Party (PDP) silẹ ni ifowosi o si darapo mo egbe All Progressives Congress (APC), o si so ìpínlẹ̀ náà pọ mọ ẹgbẹ́ to n se ijoba lọ́wọ́
Gomina fi ẹgbẹ́ náà sile pẹ̀lú àwọn Komísínà mejilelogun, o si se apejuwe ipitnnu náà gẹgẹ bi igbese ogbon lati ri daju wi pe ìdúróṣinṣin, ìdàgbàsókè, ati aisiki wa fun ìpínlẹ̀ Adamawa fun igba pipẹ.
Nígbàtí ó ń bá àwọn ará ìlú sọ̀rọ̀ nínú ifiranṣẹ , Gómìnà náà ranti awọn aṣẹ ti o lagbara ti a fun ijọba rẹ ni ọdun 2019 ati 2023, o si ṣe akiyesi pe atilẹyin awọn eniyan fi ẹru iwa-rere le ijọba lati duro ni ifaramo si adehun awujọ rẹ.