Ní dídojúkọ àwọn ìṣòro líle koko nínú ìdìbò tí ń bọ̀, olórí ìjọba Hungary tí ó ń gbèjà Orílẹ̀-èdè Russia ń gbìyànjú láti yí àwọn olùdìbò lérò padà pé ewu tó ga jùlọ sí orílẹ̀-èdè náà kì í ṣe ìdúróṣinṣin ọrọ̀ ajé rárá ṣùgbọ́n olórí alatako rẹ̀ kò pé méjì bí kò ṣe Orílẹ̀-èdè Ukraine tí ó wà ní àdúgbò rẹ̀.
Viktor Orbán ń ṣe ìpolówó oníròyìn oníjàgídíjàgan tí ó kún fún ìròyìn èké tí ìhìn pàtàkì rẹ̀ ni pé àwọn ará Hungary yẹ kí wọ́n kọ̀ láti bá àwọn ará Europe yòókù ṣe àtìlẹ́yìn fún Orílẹ̀-èdè Ukraine lòdì sí ìkọlù Russia. Ó jiyàn pé ọ̀nà yẹn lè mú kí orílẹ̀-èdè náà di aláìlókun kí ó sì pa àwọn ọ̀dọ́ rẹ̀ ní iwájú ogun.
Àwọn àtẹ ìpolówó tí a gbé kalẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè náà fi àwọn àwòrán Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Ukraine Volodymyr Zelenskyy tí àwọn aláṣẹ Orílè-èdè Europe yíká hàn, tí ó na ọwọ́ rẹ̀ bí ẹni pé ó ń béèrè owó
Ẹ̀bẹ̀ kan tí a fi ránṣẹ́ sí gbogbo ará Hungary tí wọ́n wà ní ọjọ́ orí ìdìbò sọ wí pé ètò EU láti ran Ukraine lọ́wọ́ ní owó yóò mú ìparun ọrọ̀ ajé wá.
Àwọn ìròyìn gbogbogbòò ti Hungary, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn àdáni tí ó dúró ṣinṣin sí ìjọba Orbán, fara wé àwọn ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú òtítọ́. Wọ́n sọ wi pé Orílẹ̀-èdè Ukraine fẹ́ fa ìjà ẹ̀jẹ̀ tí ó ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ìlú rẹ̀ gùn – tí ó sì ń dìtẹ̀ mọ́ EU láti ṣe é.