Take a fresh look at your lifestyle.

Òṣèrébìnrin Ará Bìrìtikó Pẹ̀lú Nàìjíríà, Wunmi Mosaku Gba Ẹ̀bùn Ẹ̀yẹ BAFTA Tó Dára Jùlọ Fún Ti Àwọn Òṣèrébìnrin

82

 

Òṣèrébìnrin ará Bìrìtikó àti Nàìjíríà, Wunmi Mosaku, ti gba ẹ̀bùn ẹyẹ BAFTA fún òṣèrébìnrin tó dára jùlọ ní ayẹyẹ fiimu BAFTA ẹlẹ́èkọkàndínlọ́gọ̀rin fún ipa ribiribi rẹ̀ nínú fiimu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀- “Sinners”. Lọ́nà tó yanilẹ́nu, ó gba ẹ̀bùn náà nígbà tó lóyún kẹ́ri, èyí tó fi ìtàn mìíràn balẹ̀ kún fún iṣẹ́ rẹ̀.

Ọmọ ọdún mọ́kalàndinlogoji náà, tí a bí ní Nàìjíríà tí ó sì dàgbà ní Manchester, ti gba ìyìn fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà obinrin Hoodoo Annie nínú fíìmù ẹ̀rù jẹjẹ ti oloorin.

Òun ni ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì aláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ tó gba ẹ̀bùn òṣèrébìnrin tó ń ṣe àtìlẹ́yìn níbi fíìmù idije ẹyẹ Bafta.

Òṣèrébìnrin náà, tí ó tún ti fara hàn nínú eré Tẹlifíṣọ̀n Luther àti Black Mirror àti àwọn fíìmù Marvel, tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọbìnrin rẹ̀, ó sì fi kún un pé, “Ìwọ ni olùkọ́ mi tó dára jùlọ”.

Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ọdọ́mọbirin Manchester fún ọdún mokanla, ó sì ṣàpèjúwe àkókò tí ó lò níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kan lára àwọn ìrántí iyebíye rẹ”.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button