Take a fresh look at your lifestyle.

Aya Ààrẹ Gbóríyìn fún Àjọ UNICEF fún Gbígbé Ìforúkọsílẹ̀ Ọjọ́ Ìbí Ọmọ Nàìjíríà Lårugẹ

44

 

Obinrin Àkọ́kọ́ orílẹ-èdè Nàìjíríà ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Àjọ to wa fun àwọn Ọmọdé ti Àjọ (UNICEF), fún mímú àṣeyọrí tí a kọ sílẹ̀ nínú ìforúkọsílẹ̀ ọjọ ìbí tí Nàìjíríà ṣe.

Nínú ìránṣẹ́ kan tí ó fi sílẹ̀ ní ọjọ́ Ajé, Arabinrin Àkọ́kọ́ Gbóríyìn fún ajọ UNICEF àti àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ ìdàgbàsókè mìíràn fún àtìlẹ́yìn wọn fun orílẹ̀-èdè yii.

“Ajọ UNICEF kéde pé ní ọdún méjì sẹ́yìn, iye àwọn ọmọ tí a ti forúkọsílẹ̀ ọjọ ìbí wọn silè ní Nàìjíríà ti fo lala lọ sí mílíọ̀nù mẹ́rìnlá. Àṣeyọrí àgbàyanu yìí fi ìdúróṣinṣin wa hàn sí dídáàbòbò ìdámọ̀ àti ẹ̀tọ́ gbogbo ọmọ Nàìjíríà”.

Obinrin akọ̀kọ́ Nàìjíríà tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n ti ran orílẹ̀-èdè yii lọ́wọ́ latí gbogun ti arụn HIV/AIDS àti àwọn àrùn mìíràn.

Ó tẹnu mọ́ ọn pé ajọsepọ a máa dara ni gbogbo ìgbà, ó sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn alenulorọ̀ láti máa tesiwaju ninu ífọwọ́sowọ́pọ̀ wọn, kí a lè mú àwọn àrùn tó ń fa ikú lọ́pọ̀lọpọ̀ kúrò.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button