Take a fresh look at your lifestyle.

Wike Gbóríyìn Fún Ìdìbò Àlàáfíà Àti Ìwà Àwọn Olùdìbò

93

Mínísítà fún Agbègbè Olú-ìlú Nàìjíríà (FCT), Nyesom Wike, ti ṣàpèjúwe ìdìbò tí agbègbè Olú-ìlú Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí “àlàáfíà” ó sì gbóríyìn fún àwọn olùdìbò fún ìwà àlàáfíà.

‎ Mínísítà náà gbóríyìn fún wọn lẹ́yìn tó ṣe àkíyèsí ìdìbò náà ní Garki, Ààfin Olórí Karu, Karshi, Kabusa àti Keti.

‎Wike ṣàkíyèsí ìṣòro àìbìkítà àwọn olùdìbò, pàápàá jùlọ ní àárín ìlú, ó ní, síbẹ̀síbẹ̀, wí pé ìdìbò àwọn olùdìbò ní àwọn ìlú ìgbèríko jẹ́ òun ìyanu.

‎ Mínísítà náà gbóríyìn fún àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò fún rírí i dájú pé wọ́n ṣe ìdìbò náà láìsí ìṣòro.

‎Nípa iṣẹ àwọn elétò ìdìbò náà, Mínísítà náà gbóríyìn fún Àjọ Elétò Olómìnira Ìdìbò Orílẹ̀-èdè, INEC fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe.

Comments are closed.

button