Bí oṣù Ramadan àti Lẹ́nti ti ọdún 2026 ṣe bẹ̀rẹ̀ lónìí, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejì (18/02/2026), Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde yayọ pẹ̀lú Mùsùlùmí Ummah àti gbogbo ọmọlẹ́yìn Kristi jàkèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pátá.
Gómìnà fi àsìkò náà rọ àwọn ẹlẹ́sìn méjèèjì lati lo àsìkò yìí láti sún mọ Ẹlẹdàá wọn nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ojúṣe wọn sí ènìyàn.
Gómìnà, ẹni tó ṣàlàyé pé, Ọlọrun n lo àsìkò yìí tí Ramadan àti Lẹ́nti bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kan náà láti kọ́ àwọn ẹlẹ́sìn méjèèjì ni pàtàkì ìfẹ́, ìsọ̀kan, àti ìgbé ayé àlàáfíà, to sì gba wọ́n níyànjú láti di ẹ̀kọ́ yìí mú sinsin.
Bákan náà ni Gómìnà fi àsìkò yìí rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àti ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti Kristiẹni láti túbọ̀ máa ran ìṣèjọba rẹ̀ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe n ṣe bọ̀ láti ọdún 2019 ti ìṣèjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Gómìnà to àwọn ènìyàn láti fi àsìkò Ramadan àti Lẹ́nti gbé ojú sókè sí Ọlọrun nínú ádùrá fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn adarí rẹ̀, nígbà tí òun náà ṣèlérí pé ìṣèjọba òun yóò tẹ̀ síwájú láti máa fi ìfẹ́ ará ìlú síwájú ohun gbogbo.
Abiola Olowe
Ìbàdàn