Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Àti  Orílẹ̀-èdè Jámánì Ṣèlérí Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Nínú Agbára, Ààbò, Àti Ọ̀nà ojú irin

42

Ààrẹ Bola Tinubu àti Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Jámánì Friedrich Merz ti pinnu láti mú kí àjọṣepọ̀ àárín gbùngbùn lágbára sí i àti láti mú kí àjọṣepọ̀ pọ̀ sí i nínú ààbò, agbára, àti àwọn ẹ̀ka ọkọ̀ ojú irin.

Nínú ìjíròrò lórí tẹlifóònù, àwọn olórí méjèèjì náà sọ ìfẹ́ wọn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ nínú iṣẹ́ ọ̀nà àti ìdàgbàsókè ọgbọ́n.

Ìròyìn kan tí Agbẹnusọ Ààrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga, fi hàn wi pé Ààrẹ Tinubu àti Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè  Jámánì jíròrò Ìṣètò Agbára Ààrẹ, nígbà tí olórí Nàìjíríà fihàn  wí pé orílẹ̀-èdè náà yóò nílò ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ìgbéjáde agbára.

Aláṣẹ Orílè-èdè Jámánì yóò ṣetán láti pèsè ìrànlọ́wọ́ ní ti èyí, nígbà tí  ilé Ìfowopamọ́ Deutsche sọ ìfẹ́ láti ṣe ìnáwó fún iṣẹ́ náà.

Ìbáṣepọ̀ ìjọba láàárín Nàìjíríà àti Jámánì ti wà fún ohun tó lé ní ọdún ni mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.

Merz sọ  wí pé orílẹ̀-èdè rẹ̀ ń retí dídé aṣojú tuntun lati Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí Jámánì pẹ̀lú ìtara.

Ó tún tẹnu mọ́ pàtàkì iṣẹ́ ọ̀nà, ó sì pè fún ìdásílẹ̀ Ilé Àkójọ Àwọn Ohun Ìṣẹ̀dá Ńlá ti Àwọn Ọ̀nà Áfíríkà.

Comments are closed.

button