Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Ṣí Gáráàjì Ọkọ̀ Àti Àwọn Ibùsọ̀ Ìtajà 540 Ni Ọjà Bódìjà, O Pàṣẹ Ki Àwọn Ọlọ́jà Kúrò Lójúu Pópó

27

 

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣí Gáráàjì àti Ibùsọ̀ ìtajà ìgbàlódé 540, eléyìí tí Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá-Ìbàdàn kọ́ sí ọjà Bódìjà, to sì pàṣẹ ki àwọn òntàjà to wà lójúu pópó láti gba àwọn Ibùsọ̀ náà láì san owó.

Gómìnà, ẹni tó fi orúkọ Bàbálọ́jà Ọjà Bódìjà, Alhaji Sunmaila Aderemi Jimoh sọ Gáráàjì àti ibùsọ̀ ìgbàlódé náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìpinnu ìṣèjọba òun láti mú ìgbéga dé bá àyíká kárà-kátà ni ọjà náà.

Makinde tún fi kún àlàyé rẹ̀ pé ni ìwọn oṣù mẹ́fà sí àsìkò yii, ìjọba yóò kọ àwọn ibùsọ̀ ìgbàlódé míràn fún àwọn oníṣòwò tó wà ní apá Kejì òpópónà UI sí Bódìjà.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Alága Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá-Ìbàdàn, Ṣeun Olufade Lu Gómìnà Makinde lọgọ ẹnu fún àtìlẹ́yìn ti ìṣèjọba rẹ̀ ni fún àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
O wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ohùn tí Gómìnà Makinde ṣe yìí jẹ́ ijẹrii sí ìlérí tó ṣe láti mú ìrọ̀rùn dé bá àwọn oníṣòwò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Alhaji Yekeen Abbas tii ṣe Bàbálọ́jà gbogboògbò ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún àfojúsùn rẹ̀ láti kó àwọn òntàjà kúrò lójú pópó.

Nígbà tó fi ọkàn ìmoore hàn, Bàbálọ́jà Ọjà Bódìjà, Alhaji Jimoh dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Gómìnà fún ìgbésẹ láti mú kí kárà-kátà di ìrọ̀rùn fún àwọn oníṣòwò ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button