Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò Ọ̀gbìn : Àwọn Aṣòfin Ṣe Ìwádìí Lórí Àìgbesílẹ̀ Owó Ìrànwọ́

29

 

Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti ṣètò láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àbájáde Àìgbesílẹ̀ Owó Ìrànwọ́ to sunmo ìgbà Biliọnu Naira, N174.26 bilionu nínú Owó Ìrànwọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀, bí Ìgbìmọ̀ lórí Ìṣẹ̀dá àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti ń rọ àwọn Ilé Iṣẹ́, Ẹ̀ka àti Àwọn Ajọ (MDAs) àti àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ ìdàgbàsókè láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìwádìí náà.

Alága Ìgbìmọ̀ náà, Bello Ka’oje, nínú ìkéde kan ní ọjọ́ Àìkú, pe gbogbo àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba àti àwọn alenulọ́rọ̀ láti pèsè àwọn ìwé àti ìtìlẹ́yìn tó yẹ láti rí i dájú pé ìwádìí náà péye àti pé o bọ sì kedere.

Ó ṣe àkíyèsí pé ìdádúró nínú ìgbesílẹ̀ owó tí a gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ ìdàgbàsókè àgbáyé ti mú kí àníyàn pọ̀ sí i lórí àìní oúnjẹ, pàápàá jùlọ lẹ́yìn ìkéde Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nípa ìpolongo pajawiri lórí ààbò oúnjẹ ní oṣù Keje ọdún 2023, ìgbésẹ̀ kan tí ó fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìtọ́jú iṣẹ́ àgbẹ̀ tí àwọn olùfúnni ní ìrànlọ́wọ́.

Ka’oje sọ àníyàn ńláǹlà pé owó náà wà ní àkókò àti pé ìdádúró ìgbésílẹ̀ ti mú kí àwọn àgbẹ̀ pàdánù àkókò ìgbìn, èyí tó yọrí sí ìdínkù nínú ìkórè ọdún 2025 àti pé ó ń fa ewu ńlá sí àsìkò iṣẹ́ àgbẹ̀ ọdún 2026.

Ó tún kìlọ̀ pé nǹkan bí igba mílíọ̀nù Dola, $200 nínú owó àjọ AfDB àfikún lábẹ́ ètò Ìnáwó tí Ó da lórí àbájáde lè wà nínú ewu nítorí àìṣe àwọn ìtọ́jú ìṣáájú.

Ó sọ pé, “Ìṣòro àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ń béèrè fún ìdúróṣinṣin láti rí i dájú pé gbogbo ìgbésẹ̀ ni a gbé kalẹ̀ láti lè gba ẹ̀ka iṣẹ́ àgbẹ̀ orílẹ̀-èdè náà là àti láti rí i dájú pé oúnjẹ wà ní ààbò.”

Nítorí náà, Ìgbìmọ̀ náà rọ gbogbo àwọn alenulọ́rọ̀ àti àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba tó báramu tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ láti tú owó sílẹ̀ àti láti ṣe àwọn ìgbésẹ̀ náà láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Orílẹ̀-èdè láti mú gbogbo ìdènà tí ó ń dí ìlọsíwájú lọ́wọ́ kúrò.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button