Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ West Ham Gbá Ọ̀mìn Pẹ̀lú Ikọ̀ Manchester United Ní Pápá Ìṣeré London

28

Ìbẹ̀rẹ̀ pípé fún olùdarí Fìdíẹ Michael Carrick ti parí, bí Manchester United ṣe tà ọ̀min Ookan sì Ookan (1-1) pẹlu ikọ̀ West Ham tí wọ́n ti wà ní bebe ipadalọlé  ní ìdíje Premier Liigii wọn, ní Pápá Ìseré London ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Ìṣẹ́jú marunlelogoji àkọ́kọ́ jẹ́ ti ògbóǹtarìgì olùgbèjà láti ọwọ́ Nuno Espírito Santo ti iko West Ham ti kò fún ikọ̀ Manchester United ní aaye fun ìkọlù.

Ikọ̀ West Ham yí ìdíje náà padà ní ìṣẹ́jú márùn-ún sí abala ìdajì kejì  lẹ́yìn ìkọlù àtúnṣe tí ó wúni lórí bí Jarrod Bowen ṣe fi bọ́ọ̀lù sọwọ́ si agbábọ́ọ̀lù àárín, Tomáš Souček to yọ̀ láàárín àwọn olùgbèjà láti gbá bọ́ọ̀lù taara sinu àwọ̀n kọjá Goli Lammens.

Benjamin Sesko ti ikọ̀ Manchester United dáa padà nígbà ti idije fẹ parí ní ayò bá yọrí sí ọkan sì oókan (1-1)  láti pa ikọ̀ West Ham United to wà ni ipò kejidinlogun lórí tábìlì lẹ́nu mọ́.

Manchester United ni ami ayò marunlelogoji, n fi àmì ayò kan ju ìkọ̀ Chelsea to lọ gba omin méjì sì meji( 2-2) pẹlu Leeds United.

Àwọn abajade èsì Premier Liigii ti ọjọ Isẹgun ní wọnyi;

Chelsea, méjì sì meji( 2-2) Leeds United

Everton ookan sì meji (1-2) Bournemouth

Tottenham Hotspur  ookan sì meji (1-2) Newcastle United

West Ham, Ookan sì Ookan (1-1)  Manchester United.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button