Bendel Insurance ṣe ìyà fún ikọ́ Enyimba FC 2-0 nínú ìpàdé wọn nínú ìdíje ‘Nigeria Premier Football League NPFL’, èyí tó ṣe ìwúrí àti ìrètí fún wọn lójúnà láti kópa nínú ìdíje CAF Champions League tàbí CAF Confederation Cup ní sáà igbábọ́ọ̀lù tó mbọ̀, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní Pápá ìṣeré Samuel Ogbemudia ní Benin, Ìpínlẹ̀ Edo.
Alex Oweilayefa ti Bendel gbá bọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ wọlé ní ìṣẹ́jú mẹ́tadínlọ́gbọ̀n (27 mins).

Efe Ubiomo fi ìkejì sí ní déédé ìṣẹ́jú mẹ́rindínlọ́gọ́rin (76 mins) láti fi àbájáde náà hàn pé wọ́n tí borí láìsí iyèméjì.

Gbogbo ìgbìyànjú Enyimba láti dá àwọn ayò náà padà ló bọ si paboo bí Bendel Insurance ṣé dúróṣinṣin.

Àwọn eré ìdárayá ọjọ́ Àìkú (All WAT)
Kano Pillars vs Remo Stars (3:30pm)
Abia Warriors Vs Rangers International (4:00pm)
Plateau United Vs Kwara United (4:00pm)
Ikorodu City Vs Niger Tornadoes (4:00pm)
Wikki Tourist Vs Katsina United (4:00pm)
Warri Wolves Vs El-Kanemi Warriors (4:00pm)
Kun Khalifat FC Vs Shooting Stars (4:00pm)
Nasarawa United Vs Bayelsa United (4:00pm).