Àwọn Òṣìṣẹ́ ní ẹ̀ka iwakùsà yanrìn odò ní Nàìjíríà ti rọ Àjọ ‘National Inland Waterways Authority (NIWA)’ láti ṣé ìtọ́sọ́nà lórí òfin àti ìlànà lórí odò Niger, wọ́n ṣàfihàn òfin onígbá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ìjọba àpapọ̀ àti tí ìpínlẹ̀ tó wọ́pọ̀.Àwọn Olùwakùsà Yanrìn Ń Wá Kí Ìjọba Tán Ìmọ́lẹ̀ Sí Òfin Lórí Odò ‘Niger’
Àwọn ipasẹ̀ odò tí ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe pàtàkì fún ìkọ́lé, ìṣòwò, àti ìgbésí ayé, pàápàá jùlọ ní àwọn àgbègbè omí tí ìpínlẹ̀ Anambra.
Ní nkán bíi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn olùwakùsà yanrìn ní etí odò Niger ṣàfihàn ìrújú ètò àti ìlànà láàrín àwọn aláṣẹ tí ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀, wọn sì fẹ́ kó hàn kedere fún ìrọ̀rùn iṣẹ́ ṣíṣe, ọrọ-ajé àti ìṣòwò.
Ní Onitsha, ibùdó ìṣòwò pàtàkì kan, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn olùwakùsà yanrìn àti àwọn awakọ̀ agbeyanrin (tipper drivers) ṣe ìwọ́de ránpẹ́ lọ sí Ilé-iṣẹ́ ‘National Inland Waterways Authority NIWA’ ní ọjọ́ Ẹtì.
Ìfihàn náà, tí ó ní àwọn olùkópa tó tó igba (200 protesters), pẹ̀lú èrò láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ìlànà àti ìtọ́sọ́nà nípa iṣẹ́ wọn.
Comments are closed.