Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Asòfi Èkó Ti Pàsẹ Kí Ìjọba Fòpin Sí Isé Ile Wíwó Tó Ń Lọ Lọ́wọ́ Ní Agbègbè Makòko

19

 

Ilé Igbimo Asofin Ìpínlè Èkó ti pàse kí ìjoba fòpin sí isé Ile wíwó tó n lo lówó ní agbègbè Makòko légbe odo Òsà ní Ìpínlè naa.

Asòfin Noheem Adams tí ó jé Alága Ìgbìmò tèékótó tí Olùdarí Ilé Ìgbìmò Asòfin náà, Asòfin Mudashiru Obasá gbé kalè ló sòrò yìí di mímò.

Lósè tó kojá ni ògòòrò àwon olùgbé agbègbè Makòko yìí tí wón wólé won fehónú hàn wá sí Ilé Ìgbìmò Asòfin náà.

Ìfèhònú náà lágbára débi pé, wón ní láti fowó sìnkún òfin mú àwon ajàfétòómonìyàn kan tí wón pè léjó báyìí.

Ìjoba Ìpínlè Èkó so pé, àwon ilé tí wón n wó náà wà ní ìbámu pèlú ààbò àwon olùgbé agbègbè náà nítorí abé okùn iná ni òpò wón kólé sí.

Asòfin Adams tí ó jé Olori omo egbé òsèlú tó pòjù lo nínú Ilé Asòfin náà ka àbájáde Ìgbìmò tèékótó náà léyìn ìpàdé awon tórò kàn ní gbòngàn Lateef Jakande nínú gbàgede Ilé Asòfin yìí ní Ìkejà. Ó ní:

“Lórúko Olùdarí Ilé Ìgbìmò Asòfin Ìpínlè Èkó, Asòfin Mudashiru Obasá àti gbogbo omo egbé Ilé Asòfin yìí, a pa á láse pé, kí isé ilé wíwó tó n lo lówó ní agbègbè Makòko, Oko-Àgbon àti Shogunró dúró lójú esè, títí dí ìgbà mìíràn.”

“Fún èyin olùgbé àwon agbègbè yìí, a fi da yín lójú pé, won yóò dásé ilé wíwó náà dúró báyìí, tí wón yóò sì fún àwon ti wón ti wó ilé won ní owó gbà-má-bínú”

Sáájú àsìkò náà nígbà tí wón n fi òrò wá Alága Agbègbè Ìjoba Ìbílè Yaba, Ògbéni Báyò Adéfuye, lénu wó lórí òrò náà, Alága fún Òrò Ètò Ìròyìn àti Ìtanijí nínú Ilé Asòfin yìí, Asòfin Stephen Ògúndípè sò pé, ó ye kí àgbóyé wà láti la àwon ènìyàn lóyè nípa bí won yóò se ràn wón lówó.

Agbaninímòràn Pàtàkì fún Gómìnà Sanwo-Olu fún Ètò Ìsodòtun Ilu, Òmòwé Babátúndé Olájídé tó wà níbi ìpàdé náà so pé, Ìjoba Ìpínlè Èkó yóò san owó gbà-má-bínú fún àwon olùgbé Makòko tí wón ti wólé won.

Òmòwé Olájídé so pé, Gómìnà Sanwo-Olu ti ya Mílíòònù méjì náírà sótò láti odún 2021 láti fi sàtúnse sí agbègbè Makòko tó wà léba odò kó lè wà ní ìbámu pèlú ìlànà àgbáyé.

Lára àwon olùgbé agbègbè náà tó wà níbi ìpàdé yìí fara mó àbájáde ìpàdé náà, pé, àwon kò nílò ìrànlówó àwon àjo ajàfétòómonìyàn lórí òrò náà mó.

Nínú òrò Baálè agbègbè Makòko, Shogunró àti Ìwàyà, Olóyè Yusuf Sagra, ó ní: “A wá síbí láti wá fi èdùn okàn wa hàn sí ìjoba ni, sùgbón pèlú gbogbo ohun tó selè yìí, okàn wa ti balè.”

Bákan náà ni Olóyè Oríoyè Ògúngbure fi ìdùnnú hàn sí àbájáde ìpàdé náà, pé gégé bí Ìjoba òsèlú tiwantiwa, bó se ye kí ìjoba se máa tétí sí òrò àwon ará ìlú nìyí.

Lánre Lagada-Àbáyòmí.

Comments are closed.

button