Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Àpapọ̀ Pin Owó Tó Súnmọ́ Tiriniọ̀nù Méta Fún Àwọn Ìpínlẹ̀, FCT

12

 

Ìjọba orílẹ-èdè Naijiria sọpé àwọn ti pin owó to le Tiriniọ̀nù méjì Naira- ₦2.45 trillion fún àwọn ipinle merindinlogoji pẹlu Olu ilu Naijiria ti ṣe Abuja láti oṣù kéta ọdún 2024 sì oṣù kẹjọ ọdún 2025 fún ìrànlọ́wọ́ ohun eelo àyíká àti fún ètò aabo káàkiri orílẹ-èdè yìí.

 

Èyí di mímọ̀ láti ẹnu oludamọran pataki fún ààrẹ lórí irohin tó ṣe kókó, ọgbẹni Daniel Bwala ninu ohun to na safefẹ́ lórí ẹrọ ayélujára ‘X’ rẹ̀, @BwalaDaniel.

 

Bí Bwala ṣe sọ, owó náà wà fún àwọn ipinlẹ̀ àti FCT láti tù ọna ati Biriji ṣe, àtúnṣe ilé ẹkọ àti ilé ìwòsan pẹlu írolágbára ètò aabo ni gbogbo àgbègbè orílẹ-èdè Naijiria.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button