Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Kí Fela Fún Ẹ̀bùn Ààmì Ẹ̀yẹ Ọla Àgbáyé.

21

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí ṣàpèjúwe ẹ̀bùn ‘Grammy Lifetime Achievement Award’ tí wọ́n fún aṣáájú ‘Afrobeat’ Fela Anikulapo Kuti gẹ́gẹ́ bí ìfìdí múlẹ̀ ipa rẹ̀ kárí ayé àti ipa ìpìlẹ̀ rẹ̀ nínú iṣẹ́ orin Áfíríkà òde òní.

‎ Ààrẹ Tinubu nínú ìgbóríyìn rẹ̀ sọ pé ẹ̀bùn-ọlá àgbáyé náà láti ọ̀dọ̀ Ilé-ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ nínú orin ìbílẹ̀, fi ipá Fela hàn pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ rẹ̀.

‎ Ààrẹ náà so wí pè olórin olókìkí náà ṣe àgbékalẹ̀ ipa náà nípa dídi ọmọ Áfíríkà àkọ́kọ́ láti gba ẹ̀bùn tó gbayì náà, bó tilẹ̀ jẹ́ wí pè lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni won fún

‎Ààrẹ náà tẹnu mọ́ wí pè iṣẹ́ Fela kọjá eré ìnàjú, ó tún ṣe àtúnse orin Áfíríkà kárí ayé, Ó tún rán ìran àwọn olórin òde òní lọ́wọ́ kárí ayé.

Comments are closed.

button