Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Tẹ́lẹ̀ Rí Gbóríyì Fún Ààrẹ Tinubu Látàrí Bí O Ṣé N Tó Ètò Ààbò.

371

Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fún omi ati ti o tun jẹ igbakeji Gómìnà ìpínlẹ̀ sokoto, Amọ̀fin Mukhtar Shehu Shagari ti gbé òsùbà okare fún Ààrẹ Bola Tinubu fún ẹ̀tò ààbò to péye ti Orílè-èdè Nàìjíría n ri gbà Labe ìjoba rẹ.

Mukhtar so èyí di mímọ̀ nìgbà ti o n ba àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ni ilè re ni ìpínlẹ̀ sokoto.

Ó sàlàyé wí pè o jẹ ohun ìwúrí bi Ààre ṣe gbà ọgá ọmọ ogun tí ó ti fi èyín ti tẹ́lẹ̀ ri padà láti ri wí pè ẹ̀tọ̀ ààbò wa ni ìdúróṣinṣin láì sí ìbẹ̀rù.

Ó ni Labe ìjoba Ààrẹ Tinubu ireti nbe fún ẹ̀tò ọ̀rọ́ ajé àti igbẹkẹle nínú ìjoba.

Bákanáà ọ ni Ààrẹ ri wí pè òun sá gbogbo ipá òun láti ri wí pè àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ anfààní ìjoba awarawa.

Shagari wa rọ àwọn ìjoba gbogbo láti ri wí pè wọn ṣe isẹ wọn bi ìlu ti rán wọn, ki wọn sì fi Aye gbà àwọn ọ̀dọ́ láti ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Orílè-èdè Nàìjíría

Comments are closed.

button