Gómìnà Muhammadu Inuwa Yahaya to jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Gombe ti kó àwọn ènìyàn ló ṣì Orílẹ̀-èdè Malaysia fún ìbẹ̀wọ̀ , Lára ìlérí re láti ri wí pè ètò ẹ̀kọ́, àṣà àti ìdàgbàsókè múlẹ ṣinṣin láàrin wọn.
Bákanáà ni ìbẹ̀wọ̀ náà jẹ wí pè wọn fi òkò ka pa ẹyẹ méjì, nítorí Gómìnà gbà ààmì ẹ̀yẹ fún fásítì Malaysia.
Gómìnà dúpẹ́ lọ́wọ́ Komísínà fún ìfẹ ti wọn hàn ati ìtọjú ti wọn se sí wọn.
Ó sàlàyé wí pè ìbáṣepọ̀ náà yóò fí Aye gbà ètò ẹ̀kọ́ to ye Kooro láàrin àwọn méjèèjì.
Gómìnà fi àsìkò náà ba àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Gombe ti wọ́n n kàwé sọ̀rọ̀ ni Malaysia, o rọ wọn láti kojú sí ẹ̀kọ́ wọn ki wọn fi sojú ìpínlẹ̀ àti Orílè-èdè Nàìjíría daradara.