Take a fresh look at your lifestyle.

Olubadan ní ìgbàgbọ́ nínú ìgbésẹ̀ tí Ààrẹ Tinubu gbé lórí ọ̀rọ̀ ààbò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

17

Ọba ilú Ìbàdàn, Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Gúsù Iwọ̀ Òòrùn Nàìjíríà, ba Rasidi  Ladoja, ti sọ pé àwọn ìpeniníjà àìláàbò Nàìjíríà kìí ṣe nǹkan tí kò le di àfìsẹ́yìn, tí ó mọ̀ dájú pé Ààrẹ Bola Tinubu ń gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́ láti kojú ọ̀rọ̀ náà.

Ọba kẹrinle-logoji ti Ibadan naa,sọ eyi ni ọjọ Ẹti lasiko ohun ti a le ṣapejuwe rẹ bii abẹwo mo dupẹ si Aarẹ ni Ile orilẹ-ede, ni Abuja, lẹyin ti Aarẹ lọ fun ayẹyẹ iwuye rẹ ni ọjọ kẹtadin-lọgbọn, oṣu kẹsan an.

Ọba naa sọ pe nigbati ailaabo jẹ ipeninija to nilo amojuto julọ lorilẹ-ede, igbesẹ ijọba Naijiria lọwọ lọwọ bayii labẹ idari Aarẹ Tinuba ṣafihan ifọkansi lati mu aabo ati irọrun ba gbogbo ọmọ orilẹ-ede.

 

” N o ro pe o jẹ nnkan ti a kole bori, bi o ṣe n lọ lọwọ bayii, mo nigbagbọ pe Aarẹ n rin ọna to tọ lati koju rẹ.”

Oba Ladoja wa rọ Aarẹ naa lati tunbọ fi idi agbekalẹ eto lori aabo ounjẹ ati iwosan rinlẹ, wipe nini anfaani lati lọ si ori oko ṣe pataki si ilọsiwaju ọrọ aabo ounjẹ.

Olubadan tun wa pe fun ilọsiwaju awọn amayedẹrun ilera, tẹnumọ iwulo lati ni awọn ile-iwosan to yantanti,  ti o le pese itọju to dara fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ti si n gba Ijọba apapọ niyanju lati ṣe atilẹyin ati mu awọn akitiyan rẹ jinlẹ ni awọn abala to ṣe pataki ti o da lori iwa lalaafia awọn ara ilu.

Comments are closed.

button