Take a fresh look at your lifestyle.

Manchester United fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé Casemiro ti tẹ̀ síwájú gégẹ́ bíí òpin àdéhùn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

16

Agbábọ́ọ́lù ipò ààrín fún Manchester United, Casemiro, yóò kúrò ní abala Premier League, tí sáà yí bá parí gẹ́gẹ́ bí òpin àdéhùn náà, ilé agbábọ́ọ́lù náà kéde.

Ọmọ ọdun mẹtale-lọgbọn naa le sun ọjọ naa siwaju fun ọdun kan, ṣugbọn ile agbabọọlu naa ko fẹẹ bẹẹ.

United ti kede pe ohun ko ni sun ọjọ rẹ siwaju ni Ọjọọru gẹgẹ bi ilana ọlọjọ pipẹ fun atunṣe ẹgbẹ naa. Casemiro ti beere pe ki ile iṣẹ naa fidi lilọ oun mulẹ lasiko yii.

Ipa Manchester United yoo wa lara mi titi aye,” Casemiro sọ bayii. Lati ọjọ akọkọ ti mo kuro ninu papa ifẹsẹwọnsẹ to dara yii, mo ri ifẹ gba lati Old Trafford.

Ifẹ naa ni mo n lo pẹlu awọn ololufẹ ile iṣẹ agbabọọlu to tawọn yọ yii.”

Ọmọ orilẹ -ede Brazil yii gunlẹ si Old Trafford ni oṣu kẹjọ, ọdun 2022 lati Real Madrid ni iye owo ọgọta miliọnu paundi ($80.90 million), ti olubori League URFA Champion lẹẹmarun yii si di ọgagun ipo aarin fun ẹgbẹ naa, pẹlu ami ayo mọkanle-logun ninu idije mẹrindin-aadọjọ.

Casemiro ko ipa pataki ni riran United lọwọ lati gba ife Carabao ọdun 2023, ti o fi ori gba bọọlu wọle ni ami meji si oodo aṣeyege wọn lori Newcastle United ni ipele ipari. O tun wa lara jijawe olubori ife FA United ọdun 2024.

ko i tii to asiko lati ṣe idagbere; a ṣi ni awọn iranti ti a o jọ ṣe ni oṣu mẹrin to ku yii,” o sọ bayii.

A ṣi ni ọpọlọpọ idije lati ṣe papọ; afojusun mi ni, ni gbogbo igba, lati fun ni gbogbo ohun to ba gba ni riran ẹgbẹ ni lọwọ lati ṣaṣe yọri.”

Comments are closed.

button