Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra Ọmowé Chukwuma Soludo ati àwọn ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ ti wọn ní pe Ohanaeze Ndigbo, ti fi ẹdun ọkan hàn lórí ipakoda Alága tẹlẹ rí fún ètò ìdìbò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Ọ̀mọ̀wé Humphrey Nwosu.
Wọn ní ẹni ọwọn tí o sí ṣe rẹ dẹ ojú àmí, láàrin ọdún 1993 lásìkò ìdìbò igba náà. Ọ̀mọ̀wé Humphrey Nwosu jade laye ni eni ọdún Mẹ́tàléláàdọ́rin.
Ìròyìn sọ wí pé àwọn ẹbí olóògbé ko ti fi irọyin kankan sí afẹfẹ, ṣùgbọ́n olóògbé jade laye ni ọjọ́ keji oṣù mẹwàá ọdún 2024 ni ilé ìwòsan Virginia ti Orílẹ̀-èdè U.S
Gómìnà ni ikú Alága tẹlẹ rí náà jẹ́ ohun tí o dun òun púpọ̀, ó ṣe àpèjúwe olóògbé gẹgẹ bí ènìyàn pàtàkì tó sì ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọkàn lásìkò iṣẹ rẹ.
Nínú ìwé tí akọwe fún Gómìnà kọ jáde èyí ti Gómìnà Buwọ́lù, Gómìnà dáàbá pàtàkì wí pé kí wọn sọ ilẹ iṣẹ ìjọba kan ni orúkọ olongbe náà fún ìrántí rẹ̀
Olongbe Nwosu ni o ṣe àkóso ètò ìdìbò ọjọ́ Kejìlá Oṣù keje ọdún 1993 nígbà ìdìbò Ààrẹ Ibrahim babangida.
Nwosu ṣiṣe fún àjọ Elétò Ìdìbò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Láàrin Ọdún 1989 sí 1993.