Take a fresh look at your lifestyle.

5

Ikọ̀ Junior Yellow Greens Fìdí Rẹmi Ní Igbà Kejì Sì Ọwọ Ikọ̀ Tanzania

Ikọ̀ Agbábọ́ọ̀lù Cricket orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ọjọ́ orí wọn kò kọjá Ọ̀kàndínlógun subú sọ́wọ́ ikọ̀ ti Tanzania ni ọjó Àìkú pẹlu ayo6 méjìlélógúnléọgọ́rùn ún -122-run nínú ìdíje ìperegedé Cricket fun ọdún 2026 ti àwọn ọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn kò tó ọ̀kandínlógun ní ìlú Èkó.

Akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn, Daniel Gim
sọ pé ikọ̀ òun subu yakata ni àgbàlá ilé wọn ní pápá iṣere Tafawa Balewa Cricket Oval, Onikan, ìlú Èkó, níbi ti wọn ti nilo aseyori kí wọn leè gba Tíkẹ́ẹ̀tì kanṣoṣo láti peregedé fún ìdíje àgbáyé Cricket, wọ́n tilẹ̀ ti kọ́kọ́ subú sí ọwọ ìkọ ti Nàmíbíà ní ọjọ́ Ẹtì tó kojá lọ bákannáà náà.

Ikọ̀ Nàìjíríà ló wà ní ipò ẹ̀yin lórí tábìlì, Iko Tanzania lo m leke Tábìlì pẹlu Ami ayo merin siwaju iko Kenya àti Nàmíbíà.

Ikọ̀ Junior Yellow Green ti orílẹ̀-èdè yìí n jà raburabu láti lọ fùn ìdíje ife àgbáyé ti Cricket ní igbà kejì nigba ti wọn kọkọ kópa ní igbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè South Africa ni ọdún 2020

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button