Ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Ṣe Ìdánilójú Iṣé Fún Àwọn Obìnrin.
Ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Oluremi Tinubu ti ṣe ìlérí ìdánilójú tí ran àwọn Obìnrin lọ́wọ́ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Bákanáà o sàlàyé wí pé Ààrẹ pàápàá kó gbẹyin láti ṣe Ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹ́yìn fún gbogbo àwọn Obìnrin pátápáta nípa dídì ipo mú ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìyàwó sọ èyí di mímọ̀ nígbà tí o Gbàlejò àwọn Òṣìṣẹ́ DSS. Igbákejì pátá fún àjọ otelemuye náà iyaafin Afolashade Adekayaoja ló ṣáájú àwọn òṣìṣẹ́ náà.
Ìyàwó Ààrẹ dupẹ lọwọ àwọn òṣìṣẹ́ DSS fún ìbẹ̀wọ̀ náà, o sí fí dà wón lójú wí pé pàtàkì ni àwọn Obìnrin jẹ láwùjọ àti wí pé gbogbo ipò ni àwọn Obìnrin ni anfààní sí ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Iyaafin Afolashade Adekayaoja dupẹ lọwọ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu fún atilẹyin rẹ lori àwọn Obìnrin.