Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó Pè Fún Síṣe Ètò Ìdìbò Sí Ipò Àwọn Káńsélọ̀ Tí Wọ́n Papòdà.

15

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó ti pè fún ṣíṣe ètò ìdìbò sí ipò àwọn káńsélọ̀ tí wọ́n papòdà.

Lára àwọn Àgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ tí ọ̀rọ̀ kàn ní Ìjọba ìbílẹ̀ àgbègbè ìdàgbàsókè Odi-Olówó, ìjọba ìbílẹ̀ Ṣómólú àti Ìbẹ̀jù-Lekki.

Nínú ìpàdé ìjíròrò ọ̀jọ́bọ (Thursday) ni Aṣòfin Nureni Akínsànyà ti rọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà láti béèrè pé kí Gómìnà Bàbájídé Sanwo-Olu fún Àjọ Elétò Ìdìbò ní Ìpínlẹ̀ Èkó, LASIEC láṣẹ láti ṣètò ìdìbò ní àwọn agbègbè yìí.

Ó tẹnu mọ́ ọn pé, kò yẹ kí wọ́n dun àwọn ènìyàn agbègbè tó kàn yìí ní ẹ̀tọ̀ wọn láti ní aṣojú ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yìí.

Nínú ìpinnu rẹ̀, Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mudashiru Ọbasá pàṣẹ fún Akọ̀wé àgbà Ilé Aṣòfin náà, Amòfin Ọlálékan Ọ̀náfẹ̀kọ̀ láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí Gómìnà Sanwo-Olu láti pàṣẹ fún Àjọ LASIEC láti ṣètò ìdìbò ní àwọn àwọn agbègbè tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà dárò Ọba Badagry, Ọba Aholu Babátúndé Akran tó wàjà lẹ́ni ọdún mọ́kàndíláàdọ́run (89).

Láńre Lágada-Àbáyọ̀mí.

Comments are closed.

button