Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Ṣèpàdé Pọ̀ Pẹ̀lú Gómìnà Oyo Àti Plateau

20

 

Ààrẹ Bola Tinubu ń Ṣèpàdé pọ̀ lọwọlọwọ pẹlu gomina ipinlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde, àti ti ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang ní gbọ̀ngán ìpàdé ilé ààrẹ Abuja, Olu ilu Nàìjíríà.

 

Gómìnà mejeeji pade ní gbọ̀ngán ààrẹ ní ojọ́ Ọjọ́rú ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

 

Ìpàdé náà ní ṣe pẹlu ètò òsèlú bíi àwọn ẹèèkàn oselu ti ń gbaradi fún ètò ìdìbò ọdún 2027.
Kí a ma gbagbe pé, Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau ti kuro nínú egbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC). Èyí jẹ ìgbà akọkọ ti yóò ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú ààrẹ lẹyìn ìdarapọ́ mọ́ ẹgbẹ́ tuntun.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button