Take a fresh look at your lifestyle.

Ọwọ́ Sìnkún Ilé Iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Tẹ Afurasí Adigunjalè Mẹta(3) Ní Ìlú Ìbàdàn

30

Ọwọ́ sìnkún ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ labẹ idari Ọ̀gá Ọlọ́pàá Fẹmi Haruna ti tẹ àwọn afurasí adigunjalè mẹta ní ìgboro ìlú Ìbàdàn lásìkò ti àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ náà n ṣe àyẹ̀wò àtìgbàdégbà gẹ́gẹ́ bíi ojúṣe wọn.

Ni ìbámu pẹ̀lú àtẹ̀jáde ti Alukoro ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, DSP Ayanlade Olayinka fi síta fún àwọn oníròyìn nínú èyí tó ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé àyẹ̀wò àtìgbàdégbà náà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá n gbà láti dẹkùn ìdigunjalè, ati láti mú kí ààbò gbogbo olùgbé tìbú-tòró Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dájú.

Àwọn afurasí adigunjalè mẹta náà ní: Abdulrahman, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún (19); Biodun Fatai, ẹni ọdún méjìdínlógún (18) àti Muiz Salawudeen, ẹni ọdún méjìdínlógún (18).

Àwọn ohun tí ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ká mọ́ wọn lọ́wọ́ ni Kẹ̀kẹ́ Maruwa ti kò ní nọmba ìdánimọ̀, eléyìí tó gbé èrò méjì nígbà ti ẹni tó wa Kẹ̀kẹ́ náà ṣe ẹnìkẹta.

Àtẹ̀jáde náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣe àyẹ̀wò inú Kẹ̀kẹ́ náà, wọn rí ìbọn ìléwọ́ kan, eléyìí to se àfihàn àṣeyọrí àyẹ̀wò tí ìkọ̀ ojú-lalákàn fi n sórí ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá gùn lé.

Bákan náà ni atẹjade náà ṣàlàyé pé Ọ̀gá Ọlọ́pàá Fẹmi Haruna pàṣẹ pé kí wọ́n taari àwọn afurasí adigunjalè mẹta náà àti ohun tí wọn ká mọ́ wọn lọ́wọ́ sí àkàtà ẹka ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá to n rí sí ìtọpinpin fún iṣẹ ìwádìí, nínú èyí tí àwọn afurasí náà jẹwọ́ pé àwọn tí lọ́wọ́ nínú ìwà ìdigunjalè ni ìlú Ìbàdàn àti agbègbè míràn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣáájú àsìkò yìí.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà wà ni ìpamọ́ ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá nígbà tí iṣẹ́ ìwádìí n tẹ̀ síwájú, lẹ́yìn ìgbà tí wọn yóò fi ojú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ba ilé ẹjọ́.

Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wa lu Ọ̀gá àgbà pátá, Kayode Egbetokun lọgọ ẹnu fún akitiyan àti àtìlẹ́yìn rẹ̀ to n mú kí ilé iṣẹ́ náà máa ṣe àṣeyọrí.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button