Asọ́lé Stanley Nwabali di gbajumọ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bí Super Eagles se gba ami ẹyẹ “Bronze” níbi idije Africa Cup of Nations (AFCON), nínú ayò golí wòó ki n gba síọ – Pẹnáritì pèlú ayò merin sì meji (4-2) lẹyìn ìgbà ti idije ti parí sì ọ̀mìn àwọn pẹ̀lú ikọ̀ Egypt.

Ikọ̀ Egypt ló kọ́kọ́ fẹ yẹlé wo ní pápá isere Stade Mohamed V ni Casablanca, latesẹ̀ Mohamed Salah ní igbà méjì ṣugbọn asọ́lé ikọ̀ Nàìjíríà, Nwabali àti ògbóntàrigi agbábọ́ọ̀lù, Semi Ajayi kò gbà fún.

Nígbà to ku díẹ̀ ki abala àkọ́kọ́ parí , Akor Adams fori gbe bọọlu wọlé alatako wọn sugbọn ẹrọ kọ̀mpùtà VAR kò gbàá wọlé pé Paul Onuachu ti se àsìse ko
to wọlé. Bakanna ní kété ti àbàlá keji bẹrẹ atamátàsé agbábọ́ọ̀lù fún ikọ̀ Nàìjíríà, arọ́pò Lookman náà tun gba bóòlù wọlé ṣugbọn Rẹfiri sọ pé, offside ni.

Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín ní ìparí kòsí ẹni to yẹlé wò, ayò wa di ayò golí wòó ki n gba siọ, nibiti asọ́lé Nwabali àti àwọn ògbóntàrigi agbábọ́ọ̀lù bíi Akor Adams, Moses Simon, Alex Iwobi àti Ademola Lookman ti fakọ yọ.

Asọ́lé ikọ̀ Nàìjíríà, Nwabali mú bọọlu agbábọ́ọ̀lù Egypt, Salah àti ti Marmoush láti rán ikọ̀ Nàìjíríà lọ́wọ́ láti borí. Ikọ̀ Nàìjíríà yóò kúrò Morocco pẹlu àmì ẹ̀yẹ “Bronze” pẹlu ìrètí ọtun ìgbàgbọ́ ninu ikọ̀ wọn.

” Ìbá ti nira fún mí láti tẹẹ síwájú bí akọ́ni-mọ̀ọ́gbá ti Nàìjíríà tó bá jẹ́ pé afìdí rẹmi”, Eric Chelle sọ èyí.
“Mo leè yangàn lórí àwọn agbábọ́ọ̀lù mi. Eléyìí dára báyìí.”
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san