Ẹgbẹ́ Ìpolongo Ìrètí Túntún Gbogbogbò (Renewed Hope Public Enlightenment Movement) tí tẹ̀síwájú láti mú kí ìmọ̀ àwọn aráàlú pọ̀ sí i lórí àwọn iṣẹ́ pàtàkì ti ìjọba Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ìpín kẹrin ti Ìgbìmọ̀ Ìpolongo gbogbogbò náà, olùdarí àgbà, Nuhu Abdullahi, sọ pé ètò náà ni a ṣe láti fí tó àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà létí lórí òtítọ́ àti ìjẹ́rìísí àwọn ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè lábẹ́ ìjọba tó wà ní tá lọ́wọ́lọ́wọ́.
Gẹ́gẹ́ bí Abdullahi ti sọ, Ìpín kẹrin naa ní á gbé lórí àwọn ìpolongo ìṣáájú nípa fífí àwọn iṣẹ́ ọ̀nà pàtàkì, ọkọ̀ ojú irin àti agbára tí ń mú kí ìrìnàjò yá, ìṣòwò àti ìṣọ̀kan agbègbè pọ̀ sí i ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà.
Ó tọ́ka sí iṣẹ́ ọ̀nà Ilélà (Ìpínlẹ̀ Sokoto) sí etíkun Badagry tí ń lọ lọ́wọ́, èyí tó gùn ju ẹgbẹ̀rún kìlómítà lọ, ó sì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ọ̀nà tó ní agbára jùlọ nínú ìtàn Nàìjíríà.
Ó tún tọ́ka sí iṣẹ́ ọ̀nà tó so Gembu pọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Taraba ní Àríwá Ìlà Oòrùn Nàìjíríà sí ààlà Cameroon, àti ọ̀nà ààlà Adamawa–Fufore–Mubi–Cameroon, ó sì sọ pé, “àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ti jìyà àìtọ́jú ní ọ̀pọ̀ ọdún kó tó di pé ìṣàkóso Ààrẹ Tinubu gbé ìgbésẹ̀.”
Alákòóso náà tún tọ́ka sí ìlọsíwájú lórí àwọn iṣẹ́ àjogúnbá, títí kan òpópónà epo gaasi Ajaokuta–Kaduna–Kano (AKK), èyí tí ó sọ pé “ko kọjá ọgbọ̀n sí ogójì ida ọgọ́rùn-ún lọ kí Ààrẹ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, tó sì tí dé ida ọgọrun dín márùn nínú ọgọ́rùn-ún lábẹ́ ìṣàkóso Tinubu.”
Tun ka nipa: Ààrẹ Tinubu Tún Fi Ìdúróṣinṣin Ìjọba Rẹ̀ Hàn Sí Ìgbésẹ̀ Ojúọjọ́ Ní Ìpàdé Abu Dhabi
Ó fi kún un pé ọ̀nà ojú irin Kano–Kaduna–Abuja àti iṣẹ́ ojú irin Kano–Maradi tó sopọ̀ mọ́ Niger Republic ń mú kí ipò Nàìjíríà lágbára ibùdó ìrìnnà agbègbè.
Abdullahi tẹnu mọ́ ọn pé, ìpolongo náà kò mọ sí Ìpínlẹ̀ Kano nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣe é káàkiri gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ àríwá, pẹ̀lú àwọn oníròyìn ìbílẹ̀, àwọn olùdarí lórí ìkànnì àwùjọ, àwọn olùdánimọ̀ àti àwọn olórí àwùjọ láti rí i dájú pé wọ́n dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.
Ẹgbẹ́ Ìpolongo Ìrètí Túntún Gbogbogbò náà tí kéde àwọn ètò láti túbọ̀ mú kí ìgbòkègbodò wọn jinlẹ̀ sí i ní oṣù tí ń bọ̀, gẹ́gẹ́ bí apá kan ohun tí ó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìsapá orílẹ̀-èdè láti jẹ́ kí àwọn aráàlú mọ̀ nípa ìrìnàjò ìdàgbàsókè Nàìjíríà àti láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀.