Take a fresh look at your lifestyle.

UK Yóò Dá Owó $9.5m Tí Wọ́n Jí Padà Sí Nàìjíríà ‎

89

Agbẹjọ́rò Àgbà fún Jersey, Mark Temple KC, ti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn ìmòye (MoU) pẹ̀lú Nàìjíríà láti mú kí owó tó ju $9.5 mílíọ̀nù tí wọ́n jí padà fún ìjọba Nàìjíríà fún ìrọ̀rùn, èyí tí yóò pèsè àwọn ohun èlò míràn fún àwọn iṣẹ́ ètò ìdàgbàsókè pàtàkì.

‎Èyí ni a sọ nínú ìkéde láti ọwọ́ Ìgbìmọ̀ Gíga ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sí Nàìjíríà.

‎Gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn náà ti sọ, àwọn owó tí wọ́n gbà padà yóò ṣètìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ ètò ìdàgbàsókè pàtàkì ní Nàìjíríà.

‎Agbẹjọ́rò Àgbà ti Àpapọ̀ àti Mínísítà fún Ìdájọ́ Nàìjíríà, Lateef Fagbemi nígbà tí ó ń gbà àdéhùn náà, ó sọ pé: “Ìgbàpadà àti dídá àwọn dúkìá tí wọ́n pàdánù padà, tẹnumọ́ bí àwọn ìsapá ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹpọ̀ àgbáyé rẹ̀ ṣe ń rí i dájú pé kò sí ibi ààbò fún ọrọ̀ tàbí dúkìá tí wọ́n kó lọ sí àwọn agbègbè òkèèrè.”

‎Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Bailiwick ti Jersey O sí ṣé ìdánilójú fún lílo owó tí wọ́n dá padà náà dáadáa.

‎ Èyí ṣàfihàn ìsapá Nàìjíríà láti tọ́pasẹ̀ owó tí wọ́n jí ko, gbà padà àti láti fi wọn ṣiṣẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè.

Comments are closed.

button