Take a fresh look at your lifestyle.

Ọjọ́ Ìrántí Àwọn Ọmọ-ogun Ọdún 2026 Bẹ̀rẹ̀

70

Àyajọ́ ayẹyẹ ìrántí àwọn ọmọ-ogun Ọdún 2026 ti bẹ̀rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, O bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àdúrà pàtàkì ní Mọ́sálásí Orílẹ̀-èdè ní Abuja, àwọn mọ́sálásí àárín gbùngbùn ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì, àti tí àwọn ẹgbẹ́ ológun ní gbogbo ní orílẹ̀-èdè.

‎Ayẹyẹ ọdún yìí pẹ̀lú àkọlé náà, “Ìgboyà, Ìrúbọ, àti Ìṣọ̀kan: Bíbọ̀wọ̀ fún Àwọn Akọni Wa”, tẹnu mọ́ iṣẹ́-ọwọ́, ipa àti ìrúbọ àwọn Ọmọ-ogun Nàìjíríà ní agbègbè ààbò orílẹ̀-èdè lọ́wọ́lọ́wọ́.

‎Gẹ́gẹ́ bí ìkéde tí Alága Ìgbìmọ̀ Ètò Orílẹ̀-èdè àti Olùdarí Àwọn Iṣẹ́ Àpapọ̀, Ilé-iṣẹ́ Ààbò, Arábìnrin Bosede Olaniyi ṣé. gbé jáde, ètò ọ̀sẹ̀ kan náà yóò bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹsàn-án sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kìíní, ọdún 2026, tí ó ní àwọn ìgbòkègbodò ìsìn, ìrànlọ́wọ́, ọgbọ́n àti ayẹyẹ.

Comments are closed.

button