Mínísítà fún Ìpínlẹ̀, Àgbègbè Olú-ìlú Àpapọ (FCT), Dókítà Mariya Mahmoud, tí kéde pé ìṣọ̀kan nínu ẹgbẹ́ òṣèlú ‘All Progressives Congress (APC)’, ṣàfihàn gbángba pé ẹgbẹ́ náà yóò ní ìṣẹgun nínú ìdìbò agbègbè náà ní oṣù tí ń bọ̀.
Mahmoud ṣé ìkéde yìí ní ìbẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìforúkọsílẹ̀ itanná tí ẹgbẹ́ APC ní ‘Apo Community Town Hall’, Abuja.
Lakoko tó n ba àwọn alẹnu-lọrọ sọrọ, Mahmoud fí ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí ìgbésẹ̀ náà, o ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì pàtàkì nínú ifaramọ ẹgbẹ́ náà sí igbamọra, isọdọtun, àti ifẹsẹmulẹ iṣọkan tiwantiwa.
Comments are closed.