Take a fresh look at your lifestyle.

COAS Ṣé Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Aṣíwájú Ní Ìpínlẹ̀ Niger Láti Dẹ́kun Ìpániláyà

51

Olórí Ẹgbẹ́ Àwọn Ọmọ-ogun ti mú ìsapá wọn pọ̀ sí i láti mú kí Ìpínlẹ̀ Niger dúró ṣinṣin nípa ṣíṣe ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ọba àti àwọn olórí ìbílẹ̀ nínú àtúnyẹ̀wò gbígbòòrò kán lórí ìfiránṣẹ́ àwọn ológun, ìmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ, àti ìmúrasílẹ̀ iṣẹ́ káàkiri ìpínlẹ̀ náà.

‎Gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn láti ọwọ́ Olùdarí àgbà fun ìbáṣepọ̀ Àwọn Ọmọ-ogun, Colonel Appolonia Anele, Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun, Lieutenant General Waidi Shaibu, ṣe àfihàn èyí nígbà tó ṣe ìbẹ̀wò sí Etsu Nupe àti Alága Ìgbìmọ̀ Àwọn Aláṣẹ Ìbílẹ̀ ti Ìpínlẹ̀ Niger, Ọba, Alhaji Dr Yahaya Abubakar, CFR, ní ààfin rẹ̀ ní Bida.

‎Nígbà ìbẹ̀wò náà, Olórí Ẹgbẹ́ Ọmọ-ogun ṣàlàyé pé ìfiránṣẹ́ náà jẹ́ láti ṣe àyẹ̀wò lórí ìfiránṣẹ́ ológun tí ń lọ lọ́wọ́, láti ṣàwárí àwọn àlàfo iṣẹ́, àti láti pinnu àwọn agbègbè tó nílò ìfiránṣẹ́ àwọn ọmọ-ogun afikún àti àwọn ohun èlò ìjà láti kojú àwọn ìpèníjà ààbò tí ń yọjú ní ìpínlẹ̀ náà.

Comments are closed.

button