Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Super Super Eagles Lu Ikọ̀ Mozambique Ní Àlùbami Pẹ̀lú Ayò Mẹ́rin Sí Òdo(4-0) Peregedé Sì Ipele Tó Súnmọ́ Àsekágbá Ìdíje AFCON.

137

 

Ikọ̀ Super Eagles borí ìdíje wọn ní papa isere Fes nígbà ti wọn lù alútakò wọn, Mozambique bí ẹní lu aṣọ òfì pẹ̀lú ayò mẹ́rin si òdo(4-0) tí wọ́n sì peregedé sì quarter-finals ìdíje AFCON ọdún 2025.

Ògbóntàrigi agbábọ́ọ̀lù Ademola Lookman ló kọ́kọ́ yẹlé wò ní ogún iṣẹ́jú kí atamátàsé agbábọ́ọ̀lù Victor Osimhen tó sọ di Meji(2-0) lẹ́yìn iṣẹju márùn ún ti bọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ ti wọ inú àwọ̀n kó tó di pé abala àkọ́kọ́ parí.

Ni abala èkejì, Victor Osimhen tun mi àwọ̀n ní igbà keji to fi di ayò mẹta sí odo(3-0) nígbà ti Lookman ṣe iranwọ fún ùn ní ìṣẹ́jú mẹ́tadínláàdọ̀ta.

Ikọ̀ Mozambique tilẹ̀ gbìyànjú láti dá ayò kan padà latẹsẹ̀ Geny Catamo ṣùgbọ́n adodi mú
agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagles, Calvin Bassey kò fun láàyè.

Ikọ̀ Super Eagles wa fọba lée látẹsẹ̀ ogbóǹtagì agbábọ́ọ̀lù, Akor Adams ní iṣẹju Aaidọrin lẹ́yìn tó ti ṣe ìrànwọ́ ní igbà méjì fún àwọn to gba bóòlù wọlé.

Ó wá di idije mẹ́rin ti ikọ̀ Super Eagles ti borí wayi tí wọ́n kò sì tíì pàdánù ẹyọkan soso, wọ́n sì ti ń súnmọ́ bèbè àti gba ife ẹtyẹ AFCON 2025.

Ikọ̀ Super Eagles orilẹ-ède Nàìjíríà ti wá mi àwọ̀n ní igbà Mọ́kanla(11) báyìí ní ìgbà tí ti ikọ̀ Senegal wà ní ipò Kejì pẹ̀lú Góòlù méwàá (10) ní àpapọ̀ nínú ìdíje náà. Ó ṣeéṣe ki ikọ̀ Nàìjíríà kojú ikọ̀ Algeria tàbí ilẹ olominira Congo nibi ikọ̀ orilẹ-ède mẹjọ to kẹ́yìn tí yóò wáyé ní ọjọ Ìsẹ́gun.

 

Èsì bọ́ọ̀lù AFCON Ọjọ́ Aje;

Egypt vs Benin Republic- Ayò mẹta sí oókan (3-1)

Nigeria vs Mozambique-Ayò mẹ́rin sí oókan (4-0)

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button