Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger ṣèdárò àwọn afaragbà Borgu

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

41

Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, Àringbùngbùn Arewa Nàìjíríà, Mohammed Umaru Bago, ti banújẹ́ lórí ìkọlù àwọn oníjàgídíjàgan tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Borgu, ti ìpínlẹ̀ náà, tí ó sì ń ṣàpéjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bíi ohun tó burú jàì, tí ó sì mú ìnira àti ìbànújẹ́ ọkàn bá àwọn ará ìlú tí wọ́n jókòó wọn jẹ́jẹ́.

Ninu alaye kan ti o fi sita latọwọ Akọwe Ibaraẹnisọrọ Agba rẹ, Bologi Ibrahim, Gomina naa barajẹ bi ikọlu naa ṣe mu ẹmi dani,  jiji ọpọlọpọ ara ilu gbe, ati biba awọn ohun ti awọn ara ile fi n wa jijẹ minu jẹ, ni awọn agbegbe ti awọn iṣẹlẹ yii ti waye.

Gomina Bago wa ba awọn eniyan agbegbe naa kẹdun, paapaa julọ awọn ẹbi awọn olufragba, ti o si n mu dawọn loju pe ijọba ko ni dawọn da ohun to ṣẹlẹ si wọn yii.

O wa ṣalaye pe o bani lọkanjẹ lati bẹrẹ ọdun tuntun pẹlu iṣẹlẹ ibanujẹ bi eleyi, Gomona naa wa rọ awọn aladugbo lati ni igbagbọ ki wọn o si maa sọ ireti nu. O tun wa n fi dawọn loju pe ijọba ohun n fọwọwẹwọ pẹlu ijọba apapọ ati awọn eleto aabo lati tunbọ fifi aabo mulẹ ni awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ati lati dena atiwaye iru rẹ nigba miiran.

Gomina Bago tun wa gbadura fun awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ki ọlọrun gbabọ wọn, ki awọn ti wọn jigbe pada wa wale layọ ati alaafia, ki ara awọn to farapa o ya, ki awọn ohun ti ara ile fi n wa jije mimu o pada sipo.

 

Comments are closed.

button