Cameroon borí South Africa pẹ̀lú àmì ayo 2–1 lati pèregede sí ìpele oníkọ̀ mẹ́jọ nínú ìdíje Ilẹ̀ Áfríkà (African Cup of Nations AFCON), ní ọjọ́ Àìkú ní Pápá Ìṣeré Al-Medina ní Rabat, Morocco.
South Africa bẹ̀rẹ̀ dáadáa nígbàtí ifẹsẹwọsẹ naa bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n pàdánù gbogbo àwọn ànfààní wọ́n bí aṣọle Cameroon Devis Epassy ṣé dáàbòbo ilé wọ́n.

Ni déédé ìṣẹ́jú mẹ́rinlelọ́gbọ̀n, agbábọ́ọ̀lù Cameroon James Tchamadeu gbayo kán wọlé fún ikọ rẹ̀.
Cameroon tẹ̀síwájú ní ìdajì kejì bí Christian Kofane ṣé fí orí gbá ayo míràn wọlé lẹ́ẹ̀kan síí ní iṣẹ́jú mẹ́tadínlàádọta, èyí tó fún àwọn agbábọ́ọ̀lù South Africa ní iṣẹ́ tó lé ṣeé.

Bafana Bafana gbá bọ́ọ̀lù kán padà ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín ni ìṣẹ́jú mẹ́tadínlàádọrun, bi Evidence Makgopa ṣe fakọyọ ṣùgbọ́n aṣọ kò b’ọmọyẹ mọ.

Cameroon yóò dojúkọ Morocco tó gbàlejò ìdíje náà ní ìpele ẹlẹni-mẹjọ ní ọjọ́ Ẹtì ní Stade Moulay Abdellah ní Rabat.