Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọmọ ológun ti gba àwon ará ìlú tí wón jí gbé ní ìpínlẹ̀ Borno sílẹ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

40

Àwọn ọmọ-ogun ti Operation HADIN KAI (OPHK) tún ti ṣe àṣeyọrí pàtàkì mììràn lẹ́nu iṣẹ́ wọn, nígbà tí wọ́n farabalẹ̀ kán lu àwọn oníjàgídíjàgan kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Konduga, ti Ìpínlẹ̀ Borno, léèyí tí ó yọrí sí ìgbàsílẹ̀ àwọn ènìyàn tí wọn jígbé àti ìkáwọn ọ̀daràn náà lápákò láti tún gbìyàjú iṣẹ́ láabi wọn ní agbègbè náà.

Ninu alaye kan, Oṣiṣẹ eto ibaraẹnisọrọ fun awọn Agbofinro Alajọṣepọ (Guusu Arewa) Operation HADIN KAI, Ajagun Sani Uba ṣalaye pe ni owurọ kutu ni ọjọ kẹrin, Oṣu Kini ọdun 2026, awọn ọmọ ogun, pẹlu ifọwọsowọ Ẹgbẹ Agbofinro (CJTF), koju awọn onijagidijagan ni ọna Sojiri.

Lafikun, awọn ọmọ ogun naa gba awọn ara ilu mẹta ti awọn onijagidijagan ti ji gbe silẹ. Awọn nnkan ti wọn ri gba silẹ lọwọ wọn lasiko ikọlu naa ni ibọn AK-47 ati awọn ohun ija loriṣirisi.

Awọn ọmọ ogun ṣetan, awọn eleto aabo naa tẹsiwaju lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ jakejado bi eto aabo se n yipada.

Awọn ọmọ ogun HADIN KAI ko jẹki o rẹ awọn lori ojuṣe wọn lati fọ gbogbo ijọṣepọ awọn onijagidijagan wẹwẹ, ki wọn o si mu alaafia ati ifọkanbalẹ gbilẹ ni agbegbe Guusu Arewa.

 

 

Comments are closed.

button