Gómìnà ìpínlè Ondo, Lucky Aiyedatiwa, ti pàse fún àwon elétò ààbò láti túnbọ̀ lékún ìpààrà lórí ààbò jákè kádò àwọn agbègbè àti agbègbè aginjù látàrí ìkọlù Àgọ́ ọlọ́pàá kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Ọwọ, ti Ìpínlẹ̀ Ondo, Gúúsù Iwọ̀- Oòrùn Nàìjíríà, ní òru ọjọ́ ọdún tuntun ku ọ̀la.
O sọ pe aabo jẹ ojuṣe wakati mẹrinle-logun, paapaa julọ lakoko awọn ayẹyẹ, ti o si gboriyìn fun awọn ile-iṣẹ aabo fun yiyara dide si ọrọ naa , eyiti ko jẹ ki nnkan bajẹ ṣiwaju ati ipadanu ẹmi. Bakan naa lo tun wa ṣalaye pe kosi laasigbo kankan ni Ipinlẹ Ondo o.
Gomina Aiyedatiwa sọ ni Ọjọbọ lẹhin ti o pe ipade aabo pajawiri ni Ile Ijọba ni Akurẹ, olu-ilu Ipinlẹ Ondo. Ipade naa ṣakojọpọ awọn olori awọn ile-iṣẹ aabo lati ṣe atunyẹwo isẹlẹ naa, ṣe ayẹwo bi wọn ṣe koju rẹ, ati lati ṣe awọn igbesẹ lati dena iwaye iru iṣẹlẹ naa lọjọ iwaju.
Lawal tako awọn ijabọ ori ayelujara ti n sọ nipa awọn olufaragba tabi ikọlu awọn ile ijọsin, o ṣalaye pe ko si ipadanu ẹmi ti ko si si nkankan to ṣe ile ijọsin kankan. O fikun pe awọn iwadii n lọ lọwọ lati mọ bi nnkan ṣe bajẹ si, pẹlu boya wọn ji nkan ko ninu ile ihamọra ọlọpa, ti o si kilọ pe ẹnikankan maa sọ ohun toju rẹ ko to.
“A le tii fada agba ti si pe awọn oni jagidijagan ni. Lọgan ti iwadi ba pari ti a si mu awọn eniyan, a o mọ awọn ti o wa nidi iṣẹlẹ naa,” Kọmiṣọna sọ bayii.