Take a fresh look at your lifestyle.

Lookman, Chelle Wà Lára Agbábọ́ọ̀lù Mọkànlá Tó Yarantí Jùlọ Tí Wọ́n Dárúkọ Ní Ìdíje AFCON Ọdún 2025 Ti Ilẹ̀ Adúláwọ̀

119

 

Agbábọ́ọ̀lù ará ipò iwájú Super Eagles orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Lookman àti akọ́nimọ̀ọ́gbá, Eric Chelle ní wọ́n ti kéde pé wọ́n wà lára agbábọ́ọ̀lù mọkànlá tó yarantí jùlọ ní ìpele àkọkọ tí Idije Africa Cup of Nations (AFCON), Ọdun 2025 ti ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Morocco.

 

Èyí rí bẹ́ẹ̀ látàrí bí ó se ń dá bí ẹdun, rọ̀ bí òwè tó ran orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ láti wà lókè ténté tábìlì ìsòrí ‘C’ tí wọ́n sì ti wà ní ipele kẹta tó kángun sí àsekágbá.

 

Bí akọnimọ̀ọ́gbá wọn, Eric Chelle, ṣe ńkọ́ wọn ní àwon náà ńgba ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì ń ṣe bẹbẹ lórí pápá eléyìí tó fàá tí wọn fié dè ipele ti wọ́n d yìí.

 

Lára àwọn tó tún ṣe dáradára ní idije AFCON tó ń lọ lọ́wọ́ láti ri
ògbóǹtarigì agbábọ́ọ̀lù ; Mohamed El Shenawy, Riyad Mahrez, Sadio Mané, àti Amad Diallo ti wọ́n sì ń ran ikọ̀ wọn lọ́wọ́ láti borí àwọn ìdíje wọn ti wọ́n sì ti gbé wọn dé ipele kòmọẹsẹ̀kóyọ.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

Comments are closed.

button