Mínísítà fún Ìròyìn àti Ìtọ́sọ́nà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Mohammed Idris, ti tẹnu mọ́ ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà gẹ́gẹ́ bí òun pàtàkì sí ìgboyà fún ẹnikẹ́ni láti darí bí aṣáájú réré.
Mínísítà fún Ìròyìn sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé kan tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àtijọ́ àti lọ́wọ́lọ́wọ́ láti ilé-iṣẹ́ ìròyìn rẹ̀ ní Kaduna ṣe ní ọlá rẹ̀.
Èyí ni a sọ nínú ìkéde kan tí Olùrànlọ́wọ́ Pàtàkì (Ìròyìn) fún Mínísítà Ìròyìn àti Ìtọ́sọ́nà Orílẹ̀-èdè náà, Rabiu Ibrahim fọwọ́ sí.
Nígbà tí ó ń ronú nípa ogún ọdún, Idris tẹnu mọ́ ìdàgbàsókè tó gbòòrò sí àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn rẹ̀ àti àwọn ògbóǹtagí tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú wọn.
Ó fi ìdùnnú rẹ̀ hàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn lábẹ́ ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tí wọ́n sì ti dé ipò pàtàkì, tí wọ́n ń ṣe àfikún gidigidi sí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè ní onírúurú ẹ̀ka.
O ṣé àfiwé èròngbà rẹ̀ ti ìṣàkóso Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, Idris ṣàlàyé bí ìmọ̀ràn ìtọ́nisọ́nà ṣe ń kọ́ni ní agbára, ọgbọn àti ìgbẹ́kẹ̀lé tó ń fún-ní ní ìgboyà láti darí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú.