Gomina ipínlẹ̀ Borno, Babagana Umara Zulum, ti gbàlejò ìpàdé ọ̀gọ̀rọ̀ ẹgbẹgbẹ̀run ẹ̀yà ènìyàn Kanuri ó kéré tán orílẹ-èdè mẹ́wàá láti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó wá síbi ìpàde àṣà ti Kanem-Borno tó wáyé ní ìlú Maiduguri.

Ìpàdé náà ṣe àgbájọpọ̀ Emir Mọ́kànlélọ́gọ̀jọ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn asojú ẹ̀yà Kanuri láti orílẹ̀-èdè Ghana, Sudan, Gabon, Niger, the Central African Republic, Senegal, Libya, Chad,
Cameroon, àti Benin.

Ìpéjọ̀pọ̀ náà wà fún kíkọ àti ìrólagbára ààlà orilẹ-ède kan sí òmíràn láàrin agbègbè àti ìletò àwọn ènìyàn Kanuri, àti láti tún mú kí ìdàgbàsókè wà láàárín wọn àti kí ogún àti àṣà wọn má bà parun nítorí iran ọjọ́ iwájú.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà, Gómìnà Zulum rọ àwọn akópa láti mú ètò ẹ̀kọ́, àjọṣepọ̀ ètò ọrọ̀ àjé àti ètò amúlúdùn lọ́kúnkúndùn ní ọ̀nà láti mú kí àgbègbè àwọn ìran Kanuri gbèrú sì káàkiri àgbánlá ayé. O tún kéde ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún Ẹẹ́dẹ́gbẹ̀jọ akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fà yọ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti jẹ́ ara Kanem-Borno Empire tẹ́lẹ̀, ní ọnà láti fi ìṣọ̀kan àti àjọṣepọ̀ múlẹ̀ daindain.
Ààrẹ orilẹ-ède Chad, Mahamat Idriss Déby Itno ní Gómìnà ti Lac Province, Ọ̀gágun àgbà -Major General Saleh Haggar Tidjani sojú fún níbi àpéjọ náà.
Àwọn tó tún wà níbi àpéjọ náà láti rii àwọn eniyan jànkàn bíi; Gómìnà ipinlẹ Yobe Mai Mala Buni; Ọgá àgbà ilé iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti Voice of Nigeria (VON), Mallam Jibril Baba Ndace;, pẹ̀lú ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ Federal Radio Corporation of Nigeria (FRCN), Dókítà Mohammed Bulama; igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Àm̀básẹ́dọ̀ Babagana Kingibe, Sultan ti Sokoto, Alhaji Muhammadu Sa’ad Abubakar III; Senatọ̀ Mohammed Tahir Monguno, Mohammed Ali Ndume, àti Barrister Kaka Shehu Lawan.
Àwọn tó tún péjú pésẹ̀ láti rí; Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin, Emirs àti àwọn Ọba alayé láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Borno, Kọmísọ́nà àti àwọn agbá òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Borno.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san