Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà AbdulRazaq Rọ Àwọn Aráàlú Láti Ṣ’àtìlẹ́yìn Fún-un Bí Ọdún 2026 Ṣé Bẹ̀rẹ̀

62

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara, Àárín Gbùngbùn Àríwá Nàìjíríà, AbdulRahman AbdulRazaq, ti ké sí àwọn aráàlú láti dúró ṣinṣin nínú àtìlẹ́yìn wọn fún ìṣàkóso rẹ̀ bí ọdún 2026 ṣé bẹ̀rẹ̀.

‎Ó ṣèlérí pé ìjọba yóò tẹ̀síwájú nínú ìsapá rẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá Ìlú.

‎Nínú ìránṣẹ́ ọdún túntún rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà, Gómìnà náà kí àwọn ará ìlú Kwara ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2026, ó sọ ìrètí pé ọdún náà yóò mú àwọn àǹfààní túntún àti àwọn àṣeyọrí tó ga jù wá fún àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan àti ìpínlẹ̀ náà lápapọ̀.

‎AbdulRazaq yin àwọn ará ìlú fún ìtìlẹ́yìn wọn jálẹ̀ ọdún tó kọjá, ó sì sọ pé ìṣọ̀kan wọn ti jẹ́ pàtàkì sí àwọn àṣeyọrí tí ìjọba rẹ̀ kọ sílẹ̀ láìka àwọn ìpèníjà sí.

Comments are closed.

button