Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí gbóríyìn fún Olùdámọ̀ràn Pàtàkì rẹ̀ lórí Ìṣètò Ìlànà àti Olórí Ẹ̀ka Ìpèsè Àpapọ̀ Àárín Gbùngbùn (CRDCU), Hadiza Bala-Usman, fún iṣẹ́ ìjọba tó tayọ̀ nígbà tó ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún rẹ̀.
Nínú ìránṣẹ́ ìkíni tí Agbẹnusọ Ààrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga fi ránṣẹ́, Ààrẹ ṣàpèjúwe Bala-Usman gẹ́gẹ́ bí ọmọ Orílẹ̀-èdè tó fi gbogbo ọdún tó ti lò nínú iṣẹ́ ìjọba ṣe àpẹẹrẹ iṣẹ́ ìsìn, ìrúbọ, àti ìfaradà sí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, àwọn ìsapá rẹ̀ ti mú kí àwọn ètò ìjọba lágbára sí i, ó gbé iṣẹ́ tó dá lórí ẹ̀rí lárugẹ, ó sì ti mú kí ìmúṣẹ Ìrètí túntún pọ̀ sí i.