Dọ́kítà Tony Nwoye to jẹ Ṣẹ́nítọ̀ to n sojú ìpínlẹ̀ Anambra ti bu ẹnu àtẹ lù bí wọn ṣe tí ọjà Ogbo Ogwu ti wa ni onitsha pa fún ìgbà pípẹ́ báyìí
Ó ni àwọn ilé ìtajà to to egbegberun márùn-un ni àjọ tó n mójú tó ọrọ oúnjẹ àti ògùn NAFDAC tí pa to sí n ṣe àkóbá fún karakata àti jẹ àwọn ènìyàn.
Nínú àtẹ̀jáde kan ti o jáde ni ọjọ́ ìsinmi ni Sẹ́nítọ̀ Nwoye ti sọ èyí mimo, ti o si pé ìjọba àpapọ̀ láti da sí ọ̀rọ̀ náà lásìkò ki àwọn ènìyàn ba le ni Anfààní láti pada sí ìdi ọja wọn.
Àjọ NAFDAC ti ojà náà pa ni oṣù Kejì ọdún 2025, látàrí ìròyìn wí pé wọn n ta àwọn ògùn ti ko tona ti o si ṣe àkóbá fún ìlera àwọn ènìyàn
Ṣẹ́nítọ̀ wa rọ àtúnṣe ni kíákíá ki o maa ba ṣe àkóbá fún àwọn ènìyàn ti ko mọ wọ́.