Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Òṣìṣẹ́ Elétò Aláàbò Dènà Àdó Olóró Láti Du Gbámú Ni Ìpínlẹ̀ Anambra.

33

Àwọn elétò òṣìṣẹ́ aláàbò nì ìpínlẹ̀ Anambra ti ba ìmọ̀ àwọn ènìyàn oníṣe laabi jẹ latari bi wọn ṣe dènà àdó olóró láti bí gbámú ni ìpínlẹ̀ náà 

Lásìkò tí wọn ṣe àyẹwò sí ìbi ifarapamo àwọn ènìyàn oníṣe laabi náà tó wà ni ìjọba ìbílẹ̀ Ihiala ni ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ní àṣírí náà ti ti.

Nínú àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ alukoro  fún Olọ́ọ̀pá ni ọjọ ìsinmi ni ìpínlẹ̀ Anambra, Kọ́múrádì Tochukwu Ikenga ni ìròyìn náà ti di mímọ

Ó ṣe àpèjúwe ibí ifarapamo náà gẹgẹ bí èyí o léwu pupo.

Ó ní agbègbè náà jẹ ibì ìbẹrù àti ibi ti léwu jùlọ́ láti ọdún kẹji sẹyìn báyìí nibe ni àwọn oníṣe laabi ti n da ìlú láàmú.

Ikenga ni wọn bá àdó olóró náà jè ni ọjọ́ àbámẹ́ta ni ọjọ́ kerindinlogun oṣù kàrún ọdún 2025 pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn Oloopa, ẹgbẹ́ ológun àwọn àwọn ọdẹ.

Ó ní ìwà ìbàjẹ́ náà pò to jẹ wí pé àwọn ojú ònà àti agbègbè ni won ti bajẹ tí wọn sí mú ìbẹrù ba àwọn ènìyàn.

Ó ní àwọn dupẹ wí pé lásìkò àtúnṣe  náà kò sí ìròyìn ìbànújẹ nitori kò sí ẹni ti o pàdánù emi rẹ

Ó wa fi àsìkò náà ṣe ìlérí wí pé àwọn Òṣìṣẹ́ Aláàbò yóò tẹsiwaju pẹlu iṣé takuntakun wọn láti rí wí pé ìwà ìbàjẹ́ di ohun igbagbe.

Comments are closed.

button