Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kashim Shettima nínú ọ̀rọ̀ sọ wí pé ìpínlẹ̀ Taraba jẹ ilé agbára fún ohun ògbìn ṣugbọn konsi àtìlẹ́yìn fún.
Igbákejì Ààrẹ Shettima sọ èyí di mímọ lásìkò ajọdun ohun ògbìn ọdún 2025 to waye ni Jalingo.
Ó ní Ọlọrun bukun ìpínlẹ̀ náà pèlú ohun ògbìn to yayi to sí ni agbára tí yóò mú ìdàgbàsókè ba ètò orò aje wa àti ọnà àbayọ sí ẹbí.
Shettima ni labẹ ìjọba Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu àwọn ti ṣetán láti ṣe àtìlẹ́yìn fún ìpínlẹ̀ náà
Ó ní pẹ̀lú iṣé takuntakun láti ọdọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà àṣeyọrí yóò ba ìpínlẹ̀ náà ju bi wọn ti ro náà.
Gómìnà Agbo Kefas so wí pé àyẹ̀ àti anfààní wà fún àwọn ènìyàn láti ṣiṣẹ ọgbin, nitori ètò ààbò àti àlàáfíà wa ni ìpínlẹ̀ náà.
Ó wá dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ igbákejì Ààrẹ àti gbogbo àwọn ti wọn wá sí ìbi ayẹyẹ náà.