Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka–“Nobel Laureate”, ti tẹnumọ bó ṣe se pàtàkì láti gbé èdè abínibí ilẹ̀ wá àti àṣà òjogúnbá lárugẹ, wípé ó jẹ́ ohun ìwúlò pàtàkì fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè .
Ó sọ èyí ní ọjọ́ Ajé níbi ti o ti ń dáhùn ìbéèrè láti ọdọ àwọn oníròyìn kété tó bẹ Centre for Cultural Studies and Creative Arts Ifafiti Ìlọrin wò. Àbẹwò náà jẹ ẹlẹyìí tí Ifáfitì náà fi ń sàmìn sí ayẹyẹ ọsẹ àṣà wọn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Soyinka tẹnumọ pé, èdè jẹ́ ohun gbógì fún mímọ ìran ènìyàn àti ìtàn nípa rẹ̀, ó wà gba àwọn ìran ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ láti kọ́ọ kí wọn sì tún leè sọ èdè abínibí wọn.
“Èdè jẹ́ ohun èèlò tí ó rẹwà láti sọ èròngbà wà”, ó sọ èyí. Ìkànìyàn tó kẹ́yìn fi yé wa pé Nàìjíríà ní èdè tó jẹ́ Ọ̀dúnrún.
Ó dára kí a kọ́ àwọn ede òkè òkun ti gbogbo ènìyàn mọ pé ó dára fún ìtèsíwájú ẹni-kọọkan àti ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè sùgbọ́n èyí kò gbọdọ̀ di àwọn èdè tiwa n tiwa lọ́wọ́.
Kòfẹ́sọ̀ Soyinka tún pe fún kíkọ́ àwọn èdè abínibí wa ní àwọn ilé ìwé wa pẹ̀lú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn, ẹ̀kọ́ àṣà láti lè fí orílẹ̀-èdè yìí yangàn nínú àwọn àṣà ajogunba wọn.
“Gẹgẹ bí ọmọ Adúláwọ̀, a ní láti mọ ìyí àṣà àti àmì ẹwà àṣà ìdánimọ̀ wà kí ìyí wà àti ohun ti a jẹ́, leè tẹ̀síwáju,” ó fi kun.
Síwájú si, ọjọgbọn Wahab Egbewole tó jẹ Alakoso Ifafiti Ìlọrin ṣe àpèjúwe àbẹwò ọjọgbọn Soyinka bí ìyí nlá àti àmì ìtàn tó ga fún ilé ìwé náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san