Mínísítà tó ń ri sì ọ̀rọ̀ nípa àwọn Obìnrin, Hajiya Imaan Sulaiman-Ibrahim ti kí Princess Opeyemi Bright ku oríire bí o ti fìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọdebìnrin tó kéré jùlọ Mayor ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Bí ètò ifinijoye rẹ yóò ṣe waye ni ọjó kẹẹ̀dógún, oṣù karùn ún ọmọ Ọ̀kàndínlọ́gbọ̀n ní ọjọ́ orí, Opeyemi Bright ti wa jẹ́ – Civic Mayor of Barking and Dagenham tuntun tó kéré jùlọ láti dè ipò náà.
Ó ti ní àkọọ́lẹ̀ rere láti ọmọ ọdún méjìlélógún nígbà tó jẹ Kounselọ̀ ti Borough tó kere julọ ní ọjọ́ orí.

Ní ibi ọ̀rọ̀ àkósọ níbi ìfinijoyè rẹ̀, o ṣèlérí láti gbé ìyí abẹ́lé lárugẹ, gbé onírúurú ẹyà ilẹ̀ Borough ga àti níní ìbásepọ̀ tó dára pẹlu àwọn olùgbé .
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san