Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra pẹ̀lú àjọsọpọ̀ – “Initiative for Agulu Development” ní ọnà láti ṣe ìmọ́tótó sì àwọn agbègbè ti omi wà àti àwọn àyíká rẹ àti ni ọ̀nà láti jẹ́ kí ẹ̀gbin omi dínkù, wọn ti ṣètò ìmọ́tótó ní gbogbo bèbè omi àti ètò sísa ọ̀rá, ike ní Otuocha, ìlà oòrùn ijọba ìbílẹ̀ Anambra.

Ní àkókò ètò náà, Kọmísọ́nà fún ètò àyíká ipinle Anambra, Dókítà Felix Odimegwu sọ pàtàkì eto ìmọ́tótó bèbè omi odò fún ìwúlò gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tó ń gbé nínú omi àti omi tìkálárarẹ̀ pẹ̀lú.

Dókítà Odimegwu wà ṣe ìkìlọ fún olùgbé àti arinrinajo afẹ́ láti yàgò kúrò nínú à ń dalẹ̀ sinú omí tàbí agbègbè rẹ tàbí ṣe ìdọ̀tí sì àyíká ibi tí omi tàbí odò wà nítòrí ó leè sàkóbá fun ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ẹja àti Ìlera ẹ̀dá.
Àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tó péjú pésẹ̀ lati rí; àwọn aṣàkóso àwùjọ ìlú Otuocha, Pásítọ̀ Ben Agape, Ọ̀gbẹ́ni Chike Aniukwu, àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Mínísirì ètò àyíká ìpínlẹ̀ Anambra àti àwọn olólùfẹ́ ètò àyíká ló péjú pésẹ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san